Omoba obinrin kan gbe ni ilu alayo, orewa pupo ju oruko re si nje - TopicsExpress



          

Omoba obinrin kan gbe ni ilu alayo, orewa pupo ju oruko re si nje Amoke ni ile Yoruba atijo. Orewa pupo debi pe gbogbo okunrin ilualayo niwon ko enu ife si, koda awon okunrin ilu agbegbe won gan o gbeyin. Amoke n ma bu gbogbo awon okunrin ti oba soro ife leti re koda atun pariwo lewon lori. Oro yin kan Oba ilu ti oje baba re lomi nu. Loru ojo kan, Oba ji Amoke sile o de ba so ooto oro wipe ile oko tito fun. Amoke wa jewo fun baba re wipe idi ti ohun fi ma n bu awon okunrin niwi pe ano Oba niwon fe di, wipe won o ni ife ohun denu. owa niwi pe enikeni ti o ba ni ise owo ti kosi iru re ri ni ilu alayo ni ohun maa fe. Oba wa fi ase si. Ni ojo keji, Oba pe gbogbo awon okunrin ilu jo, o de se alaye fun won pe eniti o ba fe fe omo ohun nii lati ni ise owo ti kosi iru reri ni ilu won. gbogbo Okunrin ilu pata niwon fariga aya fi awon okunrin meta kan ti oruko won nje Alani, Adisa ati Alabi. Awon meteta se ileri fun oba wipe awon ma lo ko ise owo ni ile oke lati le ma pidan. Woni pe ti awon ba padade, ki Oba ati Amoke mu ikan ninu awon latari ise ti awon ko. Awon meteta ba gbera odi ile oke, ojo meje gbako niwon fi rin irin ajo de ile oke. Alani ko ise Ariran, Adisa ko ise lati le ma di-ofe, Alabi wa ko ise joku-joku. osu meta niwon lo ni ile okere. Ni ojo ti awon meteta gba ominira, tiwon yege lenu ikose won, won wa bere irin ajo won lati pada si ilu alayo, nibi ti won ti nse awada wipe onikaluku won ni ohun ma fe amope nitori ise ti ohun ko odi dandan ki owu Oba ati Amoke lori. Ibi ti won ti se awada lowo ni Alani ba kawo mori lo kigbe pe Amoke ti ku ooo, Adisa ati Alabi bi lere wipe bawo lose mo, oni ise ti ohun ko ni, oni ohun ri ti gbogbo ilu se ipalemo ati lo sin. looto, nilu alayo, eni base alaisi, ojo naa niwon ma sin. oku kin di ojo keji, eewo ilu won ni. Loro kan, ibi ti awon meteta ti nsukun ni Alabi bani pe kani ohun ri ohun ti ologbe ohun lofe de ilu awon kiwon to sin Amoke ohun koba ji sile. Adisa bi lere wipe se ole ji oku dide ni? Alabi ni ise ti ohun ko ni. Ni adisa ba di awon mejiji lowo mu, lo bere sini poofo, ni iseju aaya, awon meteta ba gbofe de Afin oba nibi ti won ti fe lo sin Amoke. Adisa ba su re loba Oba wipe kiwon fun ohun ni iseju meta pere ki ohun fi soro si eti Amoke. Bi ere bi awada, Amoke ba dide nle bi eni ti n sun. Amoke koku moo, oko ni o ma fe nisin yii. Ibeere itan yi ni, ti e ba je Oba, tani ema fi Amoke fun gege bi Oko laarin Alani ariran, Adisa Olofe ati Alabi jokujoku ?? Eba wa da si.
Posted on: Mon, 02 Dec 2013 18:09:24 +0000

Trending Topics



"stbody" style="min-height:30px;">
We have lots of lovely theatre tickets left for this magnificent
>>>> Before you guys make any opinions about the conflict in

Recently Viewed Topics




© 2015