AWON KOKO INU IWE IROYIN WA TO JADE LONI. (7/8/2014). • - TopicsExpress



          

AWON KOKO INU IWE IROYIN WA TO JADE LONI. (7/8/2014). • Noosi kan ku ni Naijiria lana latari aisan Ebola - The Sun. • ‘Koye ki Patrick Sawyer rin arin ajo kuro ni orile-ede Liberia nigba to mo pe oun nsaisan lowo’ - Daily Independent. • Iko Boko Haram kolu Borno latari bi abenilori won se ka iye awon toti pa - The Nation. • Orile-ede Spain ti ni akosile enikan to ni arun Ebola lodo won - Vanguard. • Adamawa: Igbakeji Nyako ro ile ejo lati fun adele gomina ni iwe gbele e - National Mirror. • Ipejo iforowero(Conference panel) fi onte lu sise adalu awon Sinato - Punch. • Kosi akosile owo ajemonu awon olukoni agba(lecturers) ninu eto isuna, ijoba apapo lo so bee - The Guardian. • Ajo(Association) Yooba Dun kede awon Abenugan ti yoo maa sakoso Ajo naa - Iwe Iroyin Yooba Dun. • Ebola: Orile-ede Naijiria nbeere fun abajade ogun iwosan to peye fun awon alaarun yii lowo orile-ede Amerika - Vanguard. • Ijoba Ile America: ‘Oun to jewa logun ni lati gba awon omobinrin towa lakolo awon Boko Haram - Tribune. • Oun oro alumoni(natural wealth) ile Adulawo ko gbodo di jijigbe tabi di atowodowo, Joe Biden lo so bee - The Nation. • Egbe oselu PDP fi esun kan egbe oselu APC pe won nseto lati fi awon ‘Arabu Alurin’ sejamba ninu eto idibo Osun to nbo dede - The Sun. ERE IDARAYA. • Enyeama, Ajagun fe kopa ninu idije Champions League todun yii - Sporting Life. • Gyan, Essien wa ninu iko eleni merindinlogbon(26-man squad) ti yoo soju Ghana - Complete Sport. • Eguavoen: Keshi nilo lati tun tamora daada si - The Nation. • O seese ki egbe agbaboolu Almeria takundina Ramon Azeez lati lo darapo mo egbe agbaboolu lorile-ede Engilandi - Tribune. Too! Ao ni ri ju bayi lo fun toni, titi ti ao tun fi pade lowuro ola, emi Oludare omo Dipeolu oniroyin yin lo ngba ladura pe aridunnu wa koni dibaje o. Amin. Oodigba! ABORUBOYE!
Posted on: Thu, 07 Aug 2014 11:38:01 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015