Asegun ni gbogbo wa loni oooo gbogbo awa omo Alade. Awa omo Yoruba - TopicsExpress



          

Asegun ni gbogbo wa loni oooo gbogbo awa omo Alade. Awa omo Yoruba ni tile yoko, a ku ajinde ara toni. Oni a dara fun gbogbo wa loruko Jesu. Amin! A dupe lowo Olorun Alaaye tO mu wa ri ojo Isegun toni, adura mi nipe, gbogbo ogun aye wa ni Olorun yio ba wa wo pale patapata. E yi to ti se ko nii gbori mo lase Edumare. Asee! Gbogbo ijade-iwole wa loni, aabo Olorun to wuwo ju ewu irin lo, Eleda wa yio daa bo wa. A o lo layo, a o bo layo, a o si ko opo ibukun wa sile loruko Oluwa. Amin! Eyin eniyan mi ninu Oluwa, Iwe Korinti Kinni, ori iletala, lati ese ikinni de iketala ni A fi ranse si wa loni lati ori Ite-Ogo wa fun iyanju ati ikilo wa pe: 1 BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro. 2 Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le sí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan. 3 Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi. 4 Ifẹ a mã mu suru, a si mã seun; ifẹ kì ise ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, 5 Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; 6 Kì iyọ̀ si aisododo, sugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; 7A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. 8 Ifẹ kì iyẹ̀ lai: sugbọn biobasepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobasepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobasepe ìmọ ni, yio di asan. 9 Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. 10 Sugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti ise ti apakan yi o dopin. 11 Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: sugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ. 12 Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; sugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; sugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu. 13 Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: sugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ. Eyi ni oro naa. E jeki asasaro lori re ki a si maa muulo fun igbe aye Onigbagbo. Ki Olorun ran wa lowo. Amin loruko Jesu. ALAAFIA NI O!
Posted on: Tue, 22 Oct 2013 09:14:41 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015