WAASI FUN ASIKO RỌMADANI. ONIWAASI: Sheikn. Ibn. - TopicsExpress



          

WAASI FUN ASIKO RỌMADANI. ONIWAASI: Sheikn. Ibn. DipẹoluOludare Daudu(a.k.a Aafa Yakubu). AKORI WAASI: IPESEELẸ FUN OSU RỌMADAN. ... ỌJỌ KESAN AAWẸ. KHUTUBAH ELEEKEJI. • Ounjẹ, mimu ati sisunmọ obinrin jẹ awọn nkan ti ẹmi ba saaba. Bi akoko awẹ ba wọle, awọn nkan wọnyi ti ẹmi n fẹ ni yoo di pipati fun awọn akoko kan. • Akoko yii bakannaa ni awọn olowo maa n mọ idẹra Oluwa lori wọn nitoripe wọn gbe jijẹ ati mimu silẹ ni eyi ti wọn yoo fi mọ ohun ti n koju awọn alaini. Eleyi ni yoo si fi jẹ ki wọn tubọ dupẹ oore oluwa lori wọn. •Bakannaa awẹ yoo le esu kuro ni ara wa lataripe ẹjẹ ki yoo le rin daadaa bi igba ti a n jẹun. Nitoripe èsù n rin ni rinrin ẹjẹ ni ara ọmọ anọbi adamu ni. • Nitori awẹ, Oluwa ma n gbe royiroyi aburu, ati ibinu jinna si ẹru Rẹ, idi ni yi ti wọn fi sọ awẹ ni isọ. • Ni asiko awẹ, eniyan yoo sun mọ oluwa rẹ yoo si jinna si irọ, abosi, itajẹ-silẹ laitọ ati ijẹ owo olowo laitọ bibẹẹkọ onitọun n fi ebi pa ara rẹ ni. Annabi wipe: Ẹniti ko ba gbe jusilẹ ọrọ irọ ati fifi se isẹ se ko si erenjẹ kan ti yoo ri nibi awẹ re jupe o fi ebi ati ongbẹ pa ararẹ lasan lọ. • Saabe Annabi ti n jẹ Jaabir (Ki Oluwa yọnu sii) sọpe: bi o ba n gba awẹ, jẹ ki igbọran rẹ, oju rẹ ati ahon rẹ naa gbawẹ kuro nibi ọrọ irọ ati awọn nkan eewọ ati fifi suta kan alabagbe- ẹni. Ki o si se pẹlẹ ni awon ọjọ awẹ rẹ ki iyatọ le baa wa nibi awon ọjọ awẹ ati awọn ọjọ miran. • Ninu ise awọn salaafi ni wipe wọn a maa joko pa si mọsalasi ni asiko awẹ ni eniti n wipe. ‘A n sọ awẹ wa, a ko ni fẹnu tẹnbẹlu ẹnikan’. • Ẹniti o ba gba awẹ pẹlu awon majẹmu, irufẹ ẹnibẹ ti ba Oluwa dowopọ pẹlu pe yoo fi alujanna se ifa jẹ. • Anaabi wipe: Ilẹkun kan n bẹ ninu alujanna, orukọ rẹ n jẹ “Ar-rọyyan”. Ibẹ ni awọn alaawẹ yoo gba wọle ti ẹnikan kan kosi nii lẹtọ sii lẹyin wọn. • Ninu ẹgbawa miran, bi wọn ba ti wọle tan won yoo tii pa. • Ninu ẹgbawa miran, ẹni ba wọle lati ẹnu ilẹkun naa ti o ba si fi mu omi naa, oungbẹ ki yoo gbẹẹ mọ lailai. • Oluwa sọ ninu Hadiisi kudusi pe: Gbogbo ise ọmọ annabi Adamọ jẹ tirẹ ayafi awẹ nitoripe Emi ni yoo san ẹsan awẹ rẹ. • Ninu isesi alaawẹ ni ko sọ oriirẹ ati ohun to n kọja sinu ikun rẹ ati awọn ohun to n koojọ, ki o si maa ranti iku ni ẹniti n kọ aye ati ọsọ rẹ silẹ lati ri ile idẹra wọ. • Nitoripe alaawẹ yoo dunnu nigba ti o ba sinu ati igba ti o ba pade oluwa rẹ. Oluwa wipe: }فَمَنْ كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَالِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدًا{. “Ẹniti n ba n rankan ipade Oluwa rẹ ki o yaa se isẹ rere ki o ma si fi ẹnikan se orogun ninu ijọsin Oluwa rẹ ”. • Oluwa sa osu “Rọmadan” ni ẹsa toripe “Al-kur’an” sọ kalẹ ni osu naa. . . Ao maa tẹsiwaju lọla. Ki Ọlọun Allah Gba Gbogbo Ibadah Wa, Kosi Ṣe Aawẹ Yii Nirọrun Fun Wa. Amin.
Posted on: Thu, 18 Jul 2013 08:10:58 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015