IGBIMỌ OSEMAWE TI FẸ YAN LISA ONDO -Akintade, Akinyẹle, - TopicsExpress



          

IGBIMỌ OSEMAWE TI FẸ YAN LISA ONDO -Akintade, Akinyẹle, Awosika ati Oguntimẹhin Lo Ku Sẹnu Idije Lati owo Abdulfatai Akintayo Awon igbimo Osemawe ilu Ondo, (Osemawe-in-Council) ti n mura lati yan eni ti yoo je oye Lisa ilu Ondo, leyin iku oloye giga Bayo Akinnola. Iwadi KAKAKI ONDO fihan pe Lisa tuntun naa yoo di mimo fun gbogbo ara ilu Ondo laipe yi, nitori bi kose si Lisa ni ilu Ondo ti n fi awon aye kan sile ni aafin Osemawe, agaga, lori eto asa ati oye jije. Awon kan ti a fi oruko bo lasiri ni won so fun KAKAKI ONDO pe igbese lati yan Lisa tuntun ti de ibi giga bayi, nipa bi igbimo Osemawe se n se ayewo si akopo ise ati aseyori awon oludije merin to ku senu Idije oye Lisa naa. Won ni awon oloye giga naa ati oba Adesimbo Kiladejo dawo duro lori oro oye Lisa ni nkan bi osu meta seyin nitori won fe wo ona to joju lati gbe yiyan oloye tuntun naa gba, ati wipe won fe ki oloye giga Olusola Adeduro je oye Sasere ti won fun un, ki oun naa ba le kopa ninu idibo ti won yoo fi yan Lisa tuntun naa. Ohun kan ti won lo tun fa ifaseyin die ninu yiyan Lisa Ondo tuntun naa ni ni wahala to sele laipe yi lori oro oye Jomu ilu Ondo. Won ni igbimo Osemawe fe ki gbogbo oloye giga mararun kopa ninu idibo Lisa tuntun ohun, ki ibo ti won ba di ba le joju. Ni bayi, awon oloye merin lo ku senu Idije oye Lisa Ondo. Awon ni oloye Alex Opeyemi Akinyẹle, Lobosin ilu Ondo, oloye Isaac Folorunso Akintade, Saibi Gogou ilu Ondo, oloye Ayotunde Awosika, Lijoka ilu Ondo ati oloye Simeon Olusola Oguntimehin to je Gbogi ilu Ondo. Awon mererin ni igbimo Osemawe n se ayewo si ohun ti won ti gbe se fun Idagbasoke ilu Ondo ati ni ile Naijiria, lati le mo eni ti won yoo dibo yan gegebi Lisa ilu Ondo. Nipa iwe kika, aseyori ati sise ise fun Idagbasoke ilu Ondo, won fi ye KAKAKI ONDO pe awon oludije mererin yi ni won kunjuwon, ti won si je eni to le je oye igbakeji Osemawe Ondo naa. Won ni o kan dara lati dibo yan oloye giga Lisa Ondo ti awon ara ilu n reti, ki ariyanjiyan ma ba le waye lori eni ti o ba jawe olubori. OLUDIJE OYE LISA ONDO OLOYE ISAAC FOLORUNSO AKINTADE (J.P) Odun 1942 ni ojo karun-undinlogun osu kejo ni a bi oloye omowe Isaac Folorunso Akintade ni ilu Ondo. Omo bibi ilu Akoni Lisa Alujannu to ti gbese ni baba ti o bi oloye Isaac, nigba ti mama Oloye Folorunso, Omoobabinrin Aderosotu je omo bibi inu Oba Jisomosun Adekolurejo ti o je oba ilu ondo ri. Eyi fi han pe idile meji pataki ni oloye omowe Isaac Folorunso Akintade tan mo. Odun 1950 ni oloye bere ile-iwe alakobere ni ile iwe St. Andrew’s Primary School Ondo, o si gba iwe eri ile eko naa ni odun 1957. Leyin naa ni oloye tesiwaju ni ile-iwe Local Authority Modern School ni odun 1959. O si jade ni ile-iwe naa ni odun 1961.Lati tun le ni imo si oloye tun gba Federal Government Teacher’s Training College ti o wa ni ilu ilesa ni ipinle osun lo, ibe ni won si ti gba iwe eri oluko onipo keji “Grade II Teachers’ Certificate” ki oloye to gbona America lo lati lo wa imo kun imo. Ni ile America ni oloye ti lo ile-iwe ti a n pe ni “Armstrong High School ti o wa ni Washington DC ati ile iwe giga Federal City college ti o ti di University of District of Columbia, ibe ni oloye Folohunsho ti kawe gboye ninu imo “Economics ni odun 1972. Orile ede America fun oloye ni eko ofe lati kawe ni “Western Illinois University, Illinois” ibe naa ni o si ti kawe gboye Digir elekeji ninu imo Economics bakanaa, (Master’s Degree in Economics) ni odun 1974 oloye si gba iwe eri AIB (American institute of Banking) ni ile Washington D.C ni odun 1976. Odun 1976 naa oloye pada si orile-ede baba re ti o si bere ise pelu banki apapo orile ede yi (Central Bank of Nigeria). Ni odun 1978 ni baba tun lo wa iriri kun eyi ti o ni tele ni “Federal ministry of trade” Eyi lo si je atokun fun un, lenu owo tara re ti o ti n gba lero tipetipe. Se bi a ba rokun ti a rosa, o di dandan ki a abo fun elebute; odun 1983 ni baba feyin ti lenu ise ijoba, leyin ise takuntakun . Oloye Folorunsho Akintade je eni ti o n fi gbogbo ojo aye re wa ilosiwaju ati igbe aye irorun fun awon eniyan, o si je eni ti o ni ife ati idagbasoke ilu re lookan aya re ni gbogbo igba, kete leyin ti baba feyinti ni CBN ni o darapo mo “Famak Nigeria LTD” gege bi Alajoni ati oludari pataki. Oloye Akintade si tun je alajopin ni Ekimogun Microfinance Bank, lowolowo bayi baba oloye ni Alaga ile ifowopamo naa. Oloye Folorunsho ni alatileyin pataki fun oko akero “Famak Line” oun naa si tun ni baba isale pataki fun awon ajo awako NURTW baba si ti ran opolopo awon ti won n se agbawa oko lowo lati di oloko fun ra won. Opolopo ami eye ni awon otokulu ti fi da baba lola. Oloye Omowe Isaac Folorunsho Akintade (J P) Saibi Gogou ti ilu Ondo ti gba ami eye lati owo awon omo bibi ilu ondo ti won je akekoo ni poli offa ni ipinle kwara. (Federation of Ekimogun Student Union of Federal Polytechnics, offa, Kwara State ). Apapo Egbe Akekoo orile ede Nigerian Students (NANS) naa tu fun baba ni ami eye ni odun 2003. Ni odun 1999 ni baba gba ami eye lati owo awon UNIFEC ti O.A.U Ile-Ife. Ami eye oloselu Pataki ti o si fi aye gba alaafia ni awon Ile-Alayo ti ile-ise amohunmaworan OSRC fun oloye ni odun 2009. Baba oloye omowe Isaac Folorunsho Akintade je Gbajumo olufe ati olufokan sin tooto ni ilu ondo lati igba aye re wa, ti ko si kaare lati tun maa tesiwaju ninu opolopo awon ise, ise ati iwa omoluabi atata titi di asiko yi. OLUDIJE OYE LISA ONDO OLOYE ALEX OPEYEMI AKINYẸLE Ni ojo kerinlelogun osu kerin odun 1938 ni a bi Oloye Alex Opeyemi Akinyẹle si idile Pa Akinyẹle, eni ti o je Ajagunfeyinti. Oloye Alex Akinyẹle lo ile-iwe alakobere All Saints ni Ondo. “Gboluji Grammar School” ni ile oluji ni Oloye Alex ti lo ile iwe girama school. Bakanna ni oloye Alex Akinyẹle tun lo kawe ni St. Andrew’s College ni ilu Oyo se ni aarin obi ni a ti maa n yo ifin, ni akoko ti oloye wa ni ile-iwe St. Andrew’s college ni won yan an gege bi alabojuto akoko fun eto igbalejo (first reception perfect) ni ile eko naa. Ile Eko giga Fasiti ife ti o di Obafemi Awolowo University bayi ni oloye Alex Akinyẹle ti keko gboye ninu eko ijinle ede geesi (English language ). Leyin ikeko gboye tan ni oloye dara po mo iko asobode orile ede yi. Oloye Alex Akinyẹle ni ijoba si yan gege bi alukoro fun iko Asobode ile wa “first public relations officer” (PRO) of the Nigeria custom and excise” odun mejindinlogun ni oloye lo lenu ise iko abosede naa ki o to bo aso iko naa sile feyinti. Leyin naa ni oloye Alex Opeyemi Akinyẹle wa di ogbontagi onisowo paraku . Akowe agba fun “Nigeria Institute of Public Relations” ni igba kan ri ni oloye n se won si di Aare fun Ajo “NIPR” naa ni akoko naa. Ni asiko isejoba Aare won ni won mu irepo ba Ajo NIPR ati ile iwe giga Fasiti Eko “UNILAG” ti o wa ni Akoka. Akintiyan Oloye Alex ni asiko ijoba re gege bi Aare NIPR ni Aare ologun orile ede yi tele, General Ibrahim Badamosi Babangida se fa a yan an gege bi minisita fun eto iroyin ati asa ( Minister of Information and Culture). Opolopo oye ati ami eye ni Oloye Akinyẹle ti gba ni ile yi ati ni oke okun, lara awon oye ti siifu Akinyẹle je ni; Lisa jigan ti ondo, Bobagunwa ti ile-ikale, Jagunmolu ti Ipetu-Ijesa ni ipinle Osun,Sasere ti Efon Alaye ni ipinle Ekiti, Aare Lomofe ti Ilu Idanre, Baagbimo ti Ijebu-Ife ni ipinle Ogun, Alatunse Agbaye ti Ila Orangun ni ipinle Osun, Menewura ti ipinle Ogini, Lobosin ti Ilu Ondo, Asona Eye ti St; Augustine. Bakanna ni Oba Jona Carlos II ti orile ede Spain fii Alex Akinyẹle je Asona eye ni ilu oyinbo “melo ni a fe ka ninu eyin adepele. Obitibi oye ati ami eye ni won ti fi da baba lola. Laipe yi naa ni ajo asobode ile Naijiria,(Nigeria Customs Service) tun fun Oloye Alex Akinyele ni amin eye Pataki, fun ipa ti o ko ninu idagbasoke ise alukoro (Public Relations) ni orile ede yi. Oloye Akinyẹle ni Awon alase orile ede yi tun fi igba kan yan gege bi Alaga fun Ajo elere idaraya orile ede Nigeria (National Sports Commission (NSC)). Ni asiko ti oloye se Alaga yi ni awon aseyori ti ko sele ri de ba ere idaraya lorile ede Nigeria. Ni odun 1992, ni asiko Akinyẹle ni ile wa Nigeria gba ami eye bronze ati silver medal merin ni Barcelona Olympic 1992. Awon egbe agba boolu under 17 naa gba ife eye agbaye, iyen (under 17 world cup in Japan 1993). Ni akoko ise alaga Sir Alex Akinyẹle naa ni egbe agba boolu Super eagles naa kun oju osuwon fun igba akoko lati gba “final” nibi idije ere boolu Agbaye, iyen (USA’94). Gege bi Alaga fun “National Reconciliation Commission” ogbona-gbongbo ti o gbounje fegbe gbawobo ni Oloye Alex Opeyemi Akinyẹle n se ninu ise Alukoro (Public Relation). Pelu bi Oloye Alex Opeyemi Akinyele ti se le ni eni odun marun-un din-logorin (75 years), o si je akinkanju olufe ati eni ti o fi ife han si ilu re ti o n fi erin ati oyaya ko tomode-tagba mora. OLUDIJE OYE LISA ONDO OLOYE SIMEON OLUSOLA OGUNTIMEHIN Ojo Kejila, osu kesan, odun 1934 ni won bi oloye Simeon Olusola Oguntimehin, ni ilu Ondo. O bere ile iwe alakobere, nigba to pe omo odun mefa geere, ki o to wa lo kawe fun eko girama ni ile iwe ‘Ondo Boys High School. Odun 1954 ni oloye yipari iwe eko girama ti o si se idanwo gboye Cambridge. Leyin idanwo re ni o lo siilu eko ni ogbon ojo, osu kejila odun ti a wi yi, ti o si bere ise ni kiakia. Ki o to pari eko iwe giga re ni okan ninu awon molebi re ti salaye asiri to wa nidi ise isiro owo,(Accounting Profession), nigba to lo lo isimi lodo re. Ile ise ijoba ti o maa n won ile ni oloye Oguntimehin ti n sese nigba ti a wi yi titi di osu keje odun 1955. Leyin ti esi idanwo ti oloye yi se jade tan ni o lo si eka isiro owo ijoba, lasiko igba ti oloogbe Festus Okotie Eboh n se minisita fun eto isuna ni ilu eko. Odun 1956 ni oloye Oguntimehin se aseyori ninu idanwo re ti won si se atejade oruko re ninu iwe iroyin West African Pilot lasiko naa. Odun 1957 ni olorun ran alaanu si oloye yi, ti o si lo si ilu Oyinbo lati lo kawe ni Oxford, ti o si jawe olubori ninu gbogbo idanwo ti o se ki o to di ogbontagiri ninu isiro owo. Leyin ti o bori ninu awon idanwo naa ni o pada si orile ede Naijiria, ti o si bere ise isiro owo ni odun 1961. Oloye yi se ise takuntakun fun opolopo odun titi o fi di aare apapo fun egbe airo owo ile Naijiria,( Institute of Chartered Accountants of Nigeria). Oloye Oguntimehin tun je alaga fun opolopo ile ise nla ni orile ede yi bii, Academy Press Plc ati Smurfit Nigeria Plc. Oloye yi je eni to ni aanu omo enikejii re, ti o si feran lati maa kopa ninu awon ohun to ma mu Idagbasoke de ba oro aje ilu Ondo ati ile Naijiria lapapo.
Posted on: Sun, 24 Nov 2013 21:59:02 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015