Mo ni ti aiye ba ro enia pin, ki enia o ma ro ara re pin, nitori - TopicsExpress



          

Mo ni ti aiye ba ro enia pin, ki enia o ma ro ara re pin, nitori ti enia ba ro ara re pin, eleyi ni mo pe ni double wahala... Ẹ o ti se mọ wipe iru isepo meji wahala yi lo sẹle si ọgbẹnito wa leti odo yen ninu iwe Johannu ori karun... Araye ro pin, oun pelu ro ara re pin... Kinidi? Eredi ni wipe, gbogbo igbiyanju ati ilakaka rẹ pabo lo njasi... Yo ti wa leti odo o, pelu erongba wipe osu kẹfa ni angeli wa lodun tokoja nitorina o sese ko je wipe osu kefa/karun/keje ni yo wa lodun yi, sugbon, nigbati Olorun ko ni so fun enikan wipe asiko ti Oun yo ran angeli Oun wa ni eleyi, nitorina, angeli na ko ni wa losu karun si ekeje...o le lo wa losu kejila, lasiko ti okunrin na yo ti kuro leti odo na... Nigbamiran, okunrin yi a tile wa leti odo yi, sugbon ti o ba ku die ki o bo sinu odo na, awon ti enia won wa nitosi, won a fi gbogbo agbara wọn ju eniti won ngbe bọ sinu omi na, nitorina, iwosan ọjọ na yo tun fo arakunrin yi ru... Nigbamiran, nibiti o ba ti nse kuru-kuru lọ lati lọ wọ inu odo na, ẹniti aisan tirẹ tun buru ju ti ọkunrin yi lo, yio fi ẹsẹ kọ ọkunrin na lẹsẹ...ẹma se jẹ ki a gbagbe wipe bi aká ti se nse ni eleyi, awọn agbalagba wipe, aka ko le fun wara, sugbọn o le da wara nu, eleyi ni wipe, eniti aisan re buru ju ti ọkunrin yi lọ, nigbati o ba ti ri wipe okunrin na fẹ kọja oun, yo se ni kaka ki eku ma jẹ sese a fi se awa danu, ani kaka ti ire na yo fi jẹ ti ọkunrin yi, enito buru fun ju lọ yi yo se ni ofun onile ofun alejo, eleyi ni wipe ko ni jẹ tiẹ, kosi ni jẹ ti toun, nitoripe okunrin na yo na ẹsẹ si oju ona yo si gbe okunrin yi subu ti ko fi ni le kọja mọ...
Posted on: Tue, 22 Oct 2013 15:49:27 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015