WAASI FUN ASIKO RỌMADANI. ONIWAASI: Sheikn. Ibn. - TopicsExpress



          

WAASI FUN ASIKO RỌMADANI. ONIWAASI: Sheikn. Ibn. DipẹoluOludare Daudu(a.k.a Aafa Yakubu). AKORI WAASI: IPESEELẸ FUN OSU RỌMADAN. ỌJỌ KẸRIN AAWẸ. Eniba kọ lati sunmọ Oluwa rẹ ninu osu yii, ko le sunmọ Ọ mọ, bakannaa ati se oriire rẹ soro. Irẹ ọmọniyan, paya Oluwa rẹ ki o si maa dupe fun Un lori awọn idẹra Rẹ lori rẹ, nipa ọla ati apọnle. Ninu ikẹ Ọlọhun lori rẹ nipe, o ba araa rẹ labẹ ase Rẹ ti o si jinna si awọn nkan ti O kọ. Ẹyin ẹru Ọlọhun, ẹ lọ mọ wipe ẹ ti dojukọ osu alapọnle to kun fun ere ti ko lẹgbẹ sugbọn fun ẹniti o ba se kongẹ ọna’mọ. Osu ti ẹ dojukọ yii ni Oluwa sọ Al-kur’an kalẹ. Osu yii kun fun adipele ẹsan fun isẹ rere bakannaa fun isafọmọ kuro nibi ẹsẹ. Ibẹrẹ osu yi jẹ ikẹ, aarin ati ikẹyin rẹ wa fun aforijin ati ibọkun lorun ẹni kuro nibi ina. Ara origun ẹsin ni gbigba aawẹ ni awọn ọsan osu naa, atipe didide fun ijọsin ni awọn oru osu naa jẹ oun ti o ni ọla. Eniti o ba se awọn isẹ naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, Oluwa yoo gbọn awọn ẹsẹ rẹ danu. Laada ti o n bẹ fun ẹniti o ba se “Umura” ninu osu yii se deede ẹsan ti n bẹ fun “Haji” sise. Inu osu yii ni wọn maa n si gbogbo ilẹkun Al-Janna ti ilẹkun ina yoo si di titipa. Bakana eṣu ati awọn iransẹ rẹ yoo wa ni ori ide. Imam Bukhari ati awọn miran gba ẹgbawa ọrọ kan wa ninu “Hadiisi Abu Hurairah” pe Annabi ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba sọ pe: ’Oluwa wa sọ pe: gbogbo isẹ ọmọ Annabi Adama jẹ tirẹ, ayaafi awẹ. Nitoripe Emi ni n O San ẹsan rẹ. Awẹ gbigba jẹ gaga kuro nibi ina, ti o ba di akoko ti ẹ n gba awẹ, ẹ ma se sọ ọrọ alufansa tabi eebu. Bakannaa ti ẹniyan ba kọju ija si ọ tabi sọ ọrọ buruku si ọ, ki o sọ fun un wipe, emi jẹ alaawẹ. Mo fi ẹniti ẹmi “Muhammad” wa ni ọwọ rẹ bura, oorun ẹnu alawẹ yọ Ọlọhun ninu ju oorun “Al-Misiki” lọ. Idunu meji ni o wa fun alawẹ, nigba ti o ba n sinu, inu rẹ yoo dun bakannaa si ni nigbati o ba pade Oluwa rẹ. Ẹyin eniyan, ẹ gba awẹ pẹlu riri iletesu bakannaa ẹ ma se gba awẹ ni ọjọ meji tabi ọjọ kan saaju osu “Rọmadan” ayafi ẹni ti o ba saaba maa n gba awẹ tẹlẹtẹlẹ, bii awẹ ọjọ mọnde tabi Alamisi. Bakannaa ẹ ma se gba awẹ ni ọjọ iye meji tii se ọgbọn ọjọ ninu osu “Shaaban” ti ẹ ba se afẹku iletesu latari kurukuru. Ninu “Hadiisi Bukari” Abdullah bn Umaru ki iyọnu Oluwa maa ba wọn sọ pe: Dajudaju Annabi ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa sọ pe: ẹ ma bẹrẹ awẹ titi ti ẹ o fi ri iletesu, ti o ba pamọ fun yin ẹ ka osu pe ọgbọn. Abu Huraira naa sọ pe Annabi sọ pe bi kurukuru ba bo oju ọjọ ti ẹ ko le rii, ẹ ka Shaaban ko pe ọgbọn. Amar bun Yaasir sọ pe: ẹniti o ba gba awẹ ni ọjọ iye meji ti sẹ Baba Kọọsimu. Origun pataki ni awẹ Rọmadan jẹ ninu Isilaamu ti Ọlọhun see ni ọranyan fun awọn ẹrusin Rẹ. Oluwa ni: يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (Mo pe ẹyin onigbagbo ododo, A se awẹ ni dandan leyin lori gẹgẹ bi A ti see ni dandan lori awọn ti wọn ti lọ, ki ẹ le paya Ọlọhun). Ao Maa Tẹsiwaju Lọla. . . Ki Ọlọhun Allah gba gbogbo ibadah wa, kosi maṣe ka awọn ẹṣẹ wa siwa lọrun. Aku Ongbẹ O, Ẹmi A Ṣika. Amin.
Posted on: Fri, 12 Jul 2013 19:05:45 +0000

Trending Topics



0">Are you looking for the SAME –DAY Apostille service for NO
EL TEXTO PARA EL DIA DE HOY: Viernes 20 de septiembre Acuérdate

Recently Viewed Topics




© 2015