Ẹnìkan tí Ó Gun Ẹṣin Funfun Na Ni Jesu Kristi Revelation - TopicsExpress



          

Ẹnìkan tí Ó Gun Ẹṣin Funfun Na Ni Jesu Kristi Revelation 19 11) Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. 12) Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. 13) A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. Aṣẹ Ọ̀rọ Ọlọrun yio pa wa mọ dọjọ ologo...Amin!
Posted on: Thu, 01 May 2014 23:22:14 +0000

Trending Topics



r>

Recently Viewed Topics




© 2015