A ku ayo opin ose yi oooo gbogbo awa omo Alade. Awa omo Yoruba - TopicsExpress



          

A ku ayo opin ose yi oooo gbogbo awa omo Alade. Awa omo Yoruba lapapo, a ku afojuba ojo Jimoh Oloyin toni. Emi wa yio se pupo re laye, laaye ati lalaafia ara. Amin. E ma binu simi pe mo pe kinto de, igboke gbodo ise ifurugbin Iyinrere naa lo faa. Gbogbo wa ni a o fi Ijoba orun sere je loruko Jesu. Amin! A dupe lowo Olorun Olodumare ti O fi iso re so wa di deede asiko yi, Iso ati Aabo Re konii ka kuro lori gbogbo wa. Asee! Eyin eniyan Olorun, oro iyanju ati ikilo ti Emi Mimo fi ranse si wa loni ni a o ri ninu iwe Filipi ori ikeji, ese ikejila titi de ikerindinlogun (Philippians 2:12-16) ti o wipe: 12 Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì ise nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, sugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã sisẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri, 13 Nitoripe Ọlọrun ni nsisẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati sisẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀. 14 Ẹ mã se ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan. 15 Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye; 16 Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le sogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si se lãlã lasan. Eyi ni oro naa. E je ki a sasaro lori re ki a si telee. Ki a muulo fun igbe aye rere wa. Ki Olorun fun wa ni etiigbo ati aya igbase loruko Jesu. Amin! ALAAFIA NI O!
Posted on: Fri, 25 Oct 2013 17:48:08 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015