Aarẹ Ẹgbẹ Ajafẹto ọmọ Yoruba Ki Oloye ọdunwo - TopicsExpress



          

Aarẹ Ẹgbẹ Ajafẹto ọmọ Yoruba Ki Oloye ọdunwo Akingbulẹ Ku IṢẹ -O ni Alaanu Bii Tirẹ Ṣọwọn Nilẹ Yoruba Aare apapo egbe ajafeto omo Yoruba (Defence for Yoruba Peoples Right), Otunba Muyideen Olamoyegun ti kan sara si oloye giga Olabanji Akingbule, Odunwo ilu Ondo fun ife ti o ni si awon alaini ati fun idagbasoke ilu Ondo ati ipinle Ondo lapapo. Otunba Olamoyegun so eyi di mimo ninu iwe atejade kan ti o fi ranse si ile itewe KAKAKI ONDO lojo isegun to koja yi, nibi to ti sapejuwe oloye giga Olabanji Akingbule gegebi akoni eda ti Olorun da lati wa se aanu fun awon ti ko ni oluranlowo ati fun idagbasoke ilu Ondo. O ni ti won ba n ko itan ilu Ondo lojo iwaju, ibi to dara ni won maa ko awon ise ribiribi ti oloye giga Akingbule gbe se ni ilu Ondo. Olamoyegun ni o je ohun iyalenu fun oun ati awon egbe ajafeto omo Yoruba pe oloye Akingbule le maa na owo re lati fi tun aye awon omo ile iwe ti won je alaini se, lai se pe o je oloselu. O fi kun pe awon ogunlogo omo ile iwe ti won ti je anfani eko ofe ti oloye giga Odunwo maa n fun awon akeko lodoodun ko ni gbagbe ipa ti baba naa ko ninu aye won, nitori opolopo won ni ko ba ma ni iru anfani ti won ni naa ti oloye giga Akingbule ko ba ni eje aanu ti o je ki o maa na opolopo milionu naira fun iranlowo awon mekunnu ipinle Ondo. Olamoyegun wa gba awon oloye ati ara ilu Ondo nimoran pe ki won maa se awokose oloye giga Olabanji Akingbule, nipa riran awon alaini ati awon to ku die kaato fun, lowo ki awon naa ba le di eni pataki lojo iwaju. O salaye pe ti a ba ri eniyan mesan ti o won tun le maa se iru iranlowo ti oloye giga Odunwo ilu Ondo nse yii, gbogbo awon alaini ni yo ni anfani lati kawe de ibi ti eru ko ti ni ba won mo, ti ilu naa yoo si je okan ninu awon ti Ilosiwaju yoo maa de ba nigba gbogbo. Otunba yi tun fi asiko naa gbe oriyin fun olori egbe Afenifere, oloye Reuben Fasoranti fun ise nla ton n gbe se ni ipinle Ondo nipa sise iranlowo fun awon mekunnu ati alaini. O salaye pe oloye Fasoranti maa n ran opolopo eniyan lowo nipa fifun won ni owo, atileyin ati pipese ise fun awon ti ko ba ni ise ti won n se. Aare egbe ajafeto omo Yoruba yi wa fi kun oro re pe ohun ti oloye giga Olabanji Akingbule ati oloye Reuben Fasoranti n se fun idagbasoke awon mekunnu ile Yoruba je ibamu fun oro Olorun to wa ninu Bibeli Mimo pe ki a ni ife omo enikeji wa gegebi ara wa ati wipe, o ye ki eniyan mo pe gigun ti a ba gun oke kii se nipa mimo o se wa, bikose nipa ife Olugbala ti o fun wa ni okun ati agbara.
Posted on: Thu, 19 Sep 2013 19:09:43 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015