IBERE :- Asalam alaekun eku oro adini iberemi soki ije oni eto - TopicsExpress



          

IBERE :- Asalam alaekun eku oro adini iberemi soki ije oni eto kiaba obinrin lowo gege bi aye seri pelu bi ati wa ni ilu ti ki se muslim nkan ibere keji opo imam ti won ba ka fatia tan won oduro bie ki won to bere sura awon miran ki ato pare amin ta oti bere sura mi eketa ije awon ona wiridi bi qudiriya tabi tijan o leto emi ti mo soro yii muridi tijani nimi awon alufa mi so pe ko ni eto alaekun karamo mo foju sona fun esi masalam ATI DAHUN SI IBERE AKOKO YI NINU AAWE TI OKOJA YI BOYA EORI KA NI AOWA TUN SE ATUNTE RE OHUN NAA NIYI. IDAHUN SI IBERE AKOKO :- IDAHUN NI SOKI KO LETO KI OBINRIN MUSULUMI MAA BA OKUNRIN LOWO. IDAHUN NI IFO SI WEWE :- ORO OWO BIBA FUN OBINRIN NINU ISLAM PIN SI, ONA PIPO NITORI IYAPA ORO TI OWA LORI RE LODO AWON ALFA WA TI ANTELE ILANA WON, AOSO IWONBA TI AAYE BA GBAWA LATI SO. 1- OBINRIN KO LETO LATI BA OKUN RIN LOWO. 2- OBINRIN TUN LETO LTI BA OKUNRIN LOWO AWON TI OBIRIN LE BA LOWO NIYI :- AWON APAKAN ALFA GBA PE OBINRIN LE BA OKO RE, OMO RE, BABA RE, BABA BABA RE, BABA OKO RE, BABA BABA OKORE, ABURO OKO RE, OMO OKO RE, ABURO RE LOKUNRIN, OMO EGBON TABI OMO ABURO RE LOKUNRIN LOWO. AWON TI OBINRIN KO LETO LATI BA LOWO NIYI:- OKO ABURO RE, OKO ABURO OKORE, ATI GBOGBO AWON TI WON KOSI NINU AWON TI AKA PE OLETO KI OBAWON LOWO,. AWON APAKAN ALFA GBA PE LEYIN OKO RE NIKAN, OMO RE ATI AWON OBINRIN EGBE RE OBINRIN KO LETO LATI BA ENIKAN-KAN LOWO, NI IBAMU PELU EGBAWA ORO LATI ODO IYAWA AISHAT (R.T.A) TI OSOPE :_ ANNABI MUHAHMMED KO FI OWORE BA OWO OBINRIN KANKAN RI. (S.A.W) BAKANNA NI ORO ANNABI TI AGBO LATI ODO MUHQAL OMO YASSAR TI OSOPE:- ANNABI TI IKE ATI OLA NBE FUN SOPE KI ENI KAN NINU YIN GBE OGBIRIGIDI IRIN GBIGBONA SI OWO RE, OLOORE FUN JU PE KI OBA OBINRIN LOWO LO. NB:- PELU BI AYE SE NLO PELU BI AWON OBINRIN WA SE NJADE LO SI AJO, TABI SISE TABI DAPO MO AWUJO AWON OLOSELU ATI BEEBE LO KOJE KI ORORUN LATI LEE SALAI BA OKUNRIN LOWO, TORI OLE MU ELOMIRAN NINU WON PADANU ISE, FUN IDI EYI NI AWON APAKAN NINU AWON ALFA WA SE WOYE SI ASIKO YI PE OBINRIN LE BA OKUNRIN LOWO PELU IBOWO TI AMO SI GLOUF. OLOHUN NI ONI MIMO JULO. -------------------------------------------------------------- IDAHUN SI IBERE KEJI :- ORO DIDAKE IMAM LEYIN FATIA KI OTO KA SURAT LE ATI AIDAKE TI YIO FI KA SURAT LE, JE ORO TI AWON ALFA YAPA DIE LE LORI. SUGBON KOSI ERI KAN PATO TI OFI ESE RINLE PE ANNABI (S.A.W) NA NSEBE LORI IRUN, AMO AWON APAKAN ALFA NI OTO KI IMAM DAKE DIE, KI AWON JANMO NA LE FI KA FATIA. EYITI OWOLE JU TI OPOLOPO AWON ALFA SI FI ARA MO KODA IMAM WA MOOLIK NA (R.T.A) TUN SOBE PE, KOTO. NB:- SUGBON TI ABARI AWON IMAM TI WON NDAKE LEYIN FATIA, IRUN WON KO BAJEO, AWON TI WON KOSI DAKE NA IRUN WON KO BAJE RARA. AMO AIDAKE LEYIN FATIA TI YIO FI KA SURAT LO WOLE JU. OLOHUN NI ONI MIMO JU. -------------------------------------------------------------- IDAHUN SI IBERE KETA :- ORO NIPA WIRIDI SISE, OROPO LORI RE, SUGBON NI SOKI WIRIDI SISE KII SE ESE BEESI NI AWON TI WON NSE KII SE KAAFIRI GEGE BI ORO AWON KAN TI WON NPE AWON ONIWIRIDI NI KAAFIRI. WIRIDI JE ONA KAN TI ANGBA LATI SUNMO OLOHUN TI ASI FIN SE AWEMO ATI AFOMO OKAN WA PELU IFARA GBOLE FUN OLOHUN WA NI. GEGE BI ADUA TI ENIYAN TI YAN LAAYO TI KOLE MASE TI OSI FI OKAN BALE SI PELU IGBAGBO RE NINU OLOHUN, TI ADUA RE SI NGBA, NJE TITERA MO IRU ADUA BE NI SISE JE ESE BI, NIGBATI OJE ORUKO OLOHUN LO FI NSE ADUA. NI SOKI WIRIDI SISE KONI ESE, SUGBON ONA TI AWON KAN NGBEGBA TI KO DARA NI KI EJE KI AJOJO PE AFIYESI WON SI KI OLOHUN SE ATUNSE GBOGBO WA. OLOHUN NI ONI MIMO JU.
Posted on: Mon, 26 Aug 2013 09:49:35 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015