OHUN AMUYE TAA NILO LORILEDE NAIJIRIA. IFE NI WARA TI A NILO NI - TopicsExpress



          

OHUN AMUYE TAA NILO LORILEDE NAIJIRIA. IFE NI WARA TI A NILO NI NAIJIRIA Ife je ohun amuye,ilana iwa,apeere ise ati ona ajumokegbe to pegede julo ninu gbogbo ona ibara eni dore(relating with others);to kunfun osuwon otito,iberu Olorun,idarijini,afojufo abbl.O je ero amuwagun(perfective engine/device) to ran olukuluku eniyan lowo lati le gbe igbe aye to bojumu to si se itewogba niwaju adaniwaye.Ife a maa mu suuru,a maa lepa alaafia pelu eniyan gbogbo labe botiwu ko ri. Ife,a maa firele jujo digbadigba nitori ara re ko sugbon nitori enikeji re(i.e love is not selfish but considerate). Ife kii huwa waduwadu (in haste or seriously eager 2 achiev sth especially in a greedy manner),dipo bee a maa gbero ati ni itelorun ninu ohun ti nbe ni akoko ti n be lowo,asi maa wo ojo ola fun rere ati idagbasoke to tayo. Eni to ni ife o ni ayo ati idunnu ewe, irufe eni be a maa tujuka nitori ife nigba ti a ba muu binu a dun-un de egun sugbon a se afojufo orankoran to le waye.Nidakeji,eni ti ko ni ife ko le ni ayo.Ohun gbogbo ni n biru won ninu,won a kun fun aso,eke,ilara,ija,ika,ikunsinu,igbesan abbl. Ara mi olufe, e ba je ka je ohun teledumare fe ka je.Ife ni Olorun, nitori bee o fe ki gbogbo wa lako labo ko fife logba, ka fife saye ko ba le dara fun mutumuwa. Okan ife a maa bale nitori ko robi ro enikookan. Bi ona eniyan ba wu Oluwa bibeli fi ye mi wipe yoo mu ki awon ota re ko gbe ni irepo pelu re. Ife a maa gbele ro, a maa so ahere dile,so ile daafin, bee ni a si so afin da ibi ibale okan ti n gbe n je baale (leader) gbogbo eni Baba (God) joba le lori. Agbajo owo lafi n soya,ajeeji owo kan iyen o ku le gberu dori bo ti wu o ri. Isin wo ikoro wo,ohun a ba jijo wo gigun ni n gun. Eyi tumo si wipe orilede wa atajo agbaye (worldwide) nilo ohun ti a pe ni ife, igba yi gan ni omo eru wa le joba laafin. Sebi anikan rin ejo ni je won niya,boka ba saju,ti paramole tele,ti ojola baba won fayafa leyin tanije koju won Ominira o si laisi ife. E je ka ye n tanra wa kiri lori ohun ti o si nipo ta n se dansaki fun.Ife gan lominira taa nilo gege bi ilu to nsan fun wara ati oyin. A ti so A ti n be leyin WARA wa nu ti n se Ayo, a wa sora wa nu sabe oyinbo leekeji...WARA di WAR (ogun) nitori ko layo ninu mo, ogun lowa ku taa fi tosan torun n daso aponle fun.Ona ati para wa lekun la n ba kiri. Ore pe,asiwere eniyan gbagbe gbogbo won ta fife gbe depo niwon tun sora won daja to rini tele to n yo moni to tun ya tan to n mura ati fani laso ya. Oselu dojelu, ijoba awarawa di ijoba anparawa. Ife kuku lo sonu nitori bee ohun amuye gbogbo to n baa rin, gbogbo won pata lo ti rewale asa (died or not in place). Otafa soke yido bori,ranti wipe oju Eledumare, o tole o toko. O rinu odo, bee lo meyin oran nigboran gan koise rara. Orin gan ti mo n ko fun wa ni wipe Ominira wa nbe ninu ife aWARAwa. E Je ka Fife lo
Posted on: Fri, 15 Nov 2013 10:59:16 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015