Awọn Ọlọpa n wa Ọdaran to Lu Iyaafin Akinlọsotu ni - TopicsExpress



          

Awọn Ọlọpa n wa Ọdaran to Lu Iyaafin Akinlọsotu ni Jibiti Lati owo Kunle Olafusi Awon agbofinro ilu Ondo ti bere iwadi lorii bi odaran kan se fi ayederu nomba ero ibanisoro lu obirin opo kan, Iyaafin Margaret Akinlosotu ni jibiti owo to je egberun lona ogorin naira. Iyaafin Akinlosotu so fun KAKAKI ONDO laipe yi pe jeje ni oun joko ti oun ri pe enikan n fi nomba ilu Oyinbo pe ero ibanisoro oun, ti eni naa si wa soro bi oko aburo oun to wa ni ilu Londonu, to si wa so fun oun pe oun ti padanu iwe irinna oun. Iyaafin yi ni oun ko tete funra pe onijibiti lo n lo ayederu nomba ero ibanisoro lati fi ba oun soro. O ni eni naa, ti oun ro pe ana oun wa be oun pe okunrin kan ti oruko re n je Babatunde Oladipupo, to wa ni ilu Abuja lo fe ba oun se iwe irinna Nigeria tuntun, nitori naa, o fe gba egberun lona ogorin naira lati se ise naa fun oun. Iyaafin yi ni eni to ba oun soro naa wa rawo ebe pe ki oun lo san owo naa sinu nomba ifowopamo okunrin to wa l’abuja naa ni ile ifowopamo Access to ba sunmo o. Iyaafin Margaret Akinlosotu tesiwaju pe n se ni oun ko gbogbo owo oja ati owo ti oun fe fi san owo ile iwe awon omo oun ti oun lo san si nomba ifowopamo ti o je “0012497861,” ni oruko Babatunde Oladipupo, ni ile ifowopamo Access to wa lagbegbe Ago Itunu, ti inu oun si dun pe oun ti se ohun ti yoo mu inu oko aburo oun dun. Ohun to wa je iyalenu fun iyaafin yi ni pe, kete ti o san owo naa si ile ifowopamo naa tan ni eni naa tun pee pelu nomba ayederu naa pe ki oun tun lo san egberun lona ogorin naira miran, nitori owo ti akoko ko le to se iwe irinna naa. O ni eyi lo faa t’oun fi wa lo so fun awon molebi oun kan pe ki won ba ana oun soro pe ki o saanu oun ki o roju lo iwonba owo ti oun ko jo fun un. Ibi ti won ti n se eyi ni asiri ti tu nigba ti eni ti o wa ni ilu Londonu ti won fi oruko re lu jibiti so fun Iyaafin yi ati awon molebi pe oun ko lo pe e sori ero ibanisoro, ati wipe ko si ohunkohun to se iwe irinna oun. Iyaafin yi ni asiko yi l’oun subu ti oun si fi igbe ta pe won ti lu oun ni jibiti. Iyaafin ti isele yi sele si ni kiakia l’oun ti lo si ago olopa ni Enuowa lati fi isele naa to awon agbofinro leti, ti okan ninu awon olopa naa si tele oun lo si ile ifowopamo naa lati se iwadi nipa oruko ati awon amin idanimo arakunrin ti o ni nomba ifowopamo ti oun sanwo naa si. O ni awon osise banki naa ko jale lati fun awon ni idanimo naa, ti won si tenu moo pe afi ti awon ba lo gba iwe ase wa lowo adajo ni ile ejo giga. Akinlosotu ni eyi lo faa ti oun se wahala titi oun fi gba iwe ase lowo adajo kan ni ile ejo giga ilu Ondo to wa ni Oka, ti awon si sira mu u lo fun awon osise ile ifowopamo Access, ti awon osise naa ni awon yoo se ise le e lori, ki awon olu ile ise awon ba le fun awon ni ase lati fun awon agbofinro ni oruko ati awon ami idanimo okunrin Babatunde Oladipupo naa. Awon osise ile ifowopamo naa ti KAKAKI ONDO fe ba soro lori isele naa ni awon ko le so ohunkohun, afi ti awon ba gba ase lati owo awon oga agba lati olu ile ise awon.
Posted on: Sun, 24 Nov 2013 22:08:41 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015